*Call* : Ẹ bami dúpẹ́ o, ẹ bámi dúpẹ́, èèyàn tó mọ rírí Jehova ẹ bami dupe
*Resp* : fiyin fún Kabiyesi ológo dídán, fi'yin foba tó gbeyi fole ẹ bami dúpẹ́ /2ce.
*Call* : ohun lo dami Lola ó, ohun lọ dami Lola, àwọn kan sọ pé mo ṣeru torí ó ruwon loju
*Resp* : kò lè ye gbogbo ota alaropin wá, ohun rere tó ṣẹlẹ̀ siwa ó ru wọn loju
Kabiyesi alaye
Abamo ja ma jebi
Akemo bí oju, ọba tí ń soye, tí tún ń sorun
Ajá bí ìjì wolu olorun tí ó ṣe fija lo
Jehova ńlá aja ma lobon
A ránmo nise a tún máa bímọ lọ
Abiamo tí kìi jeki ọmọ rẹ jin sofi esu
(beats change)
*Call&resp* :
Alágbára nla
Mo dè bí ìṣe mi
A gboje ọpẹ de
Ẹ gbéra nílé ejeun
Kawa fope fi'yin folu
*Resp* : Kawa fope fi'yin Folu ó ahh, ọba tó ń bawa ṣe tí kò dawo dúró /2ce
*Call&Resp* :
oyigiyigi abanise
Ọba ti ń fi molè bora
Pitipiti nínú ola
Ọba nínú imole roro
Ajidara tó bá ọ lè da
*Resp* : Ajidara to bá ọ lè dá laye óò ah, alágbára tá ò lè di lowo
*Call&Resp* :
Gbogbo ayé ẹ wá gbo
Mo ní advice kan
Ẹ ye fojú do pé
Isegun nínú ọpẹ ó kere
Isegun nínú ọpẹ pò gidi gan
Ogun tí àdúrà kò bá ṣe
*Resp* : ogún ti àdúrà kò bá ṣe ó ah, ìyìn a yanjú rẹ kiakia
*Call&Resp* :
Je ki n lọ́jọ́ ọpẹ ó eeh
Jeki kí n lọ́jọ́ ọpẹ óò ah
Lórí oro tó wà nílè yí ọ jeki lọ́jọ́ ope
Je ki n lọ́jọ́ ope/3ce
No comments:
Post a Comment